Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

K

Kàkà kí ilẹ̀ kú, ṣíṣá ni yó ṣàá.

Kì í kan ẹni ká yẹrí.

Kí a re odò ká sùn; kí ni ará ilé yó mu?

Kí á gbé ọkọ́ so sájà ká pète ìmẹ́lẹ́; ojúgun-ún yó tán ó fikùn sẹ́hìn.

Kí á ránni níṣẹ́ ò tó ká mọ̀ ọ́ jẹ́.

Kí á tó bí ọmọdé, ẹnìkan là ḿbá ṣeré.

Kí eégún tó dé lAlágbaà-á ti ńfọ̀lẹ̀lẹ̀ jẹ̀kọ.

Kì í rẹ òòrẹ̀ kó rẹ sinsin ìdí ẹ̀.

Kì í tán nígbá osùn ká má rìí fi pa ọmọ lára.

Kí ni eégún ńwò tí kò fi òwúrọ̀ jó?

Kí ní ḿbẹ nínú isà tí yó ba òkú lẹ́rù?

Kí ni ọmọ ẹyẹ ó ṣe fún ìyá ẹ̀ ju pé kó dàgbà kó fò lọ?

Kí òyìnbó tó dé la ti ńwọ aṣọ.

Kíkú ajá, ng kò ní omitooro ẹ̀-ẹ́ lá; àìkú ẹ̀ ng kò ní pè é rán níṣẹ́.

Kìnìún ò níí ṣàgbákò ẹkùn.

Kò ka ikú: àdàbà sùú-sùú tí ńjẹ̀ láàrin àṣá.

Kò sí alápatà tí ńpa igún.

Kò sí bí igbó ṣe lè ta kókó tó, erin óò kọjá.

Kò sí èrè nínú-u “Gba owó kà.”

Kò sí ewu lóko, àfi gìrì àparò.

Kò sí ẹni tí Ọlọ́run ò ṣe fún, àfi ẹni tó bá ní tòun ò tó.

Kò sí ibi tí kò gba ọ̀gọ̀; ọ̀lẹ layé ò gbà.

Kò sí ibi tí ọwọ́-ọ̀jà erin ò tó.

Kò sí ikú tí kò rọ adìẹ lọ́rùn.

Kò sí ohun tí ńti òkè bọ̀ tí ilẹ̀ ò gbà.

Kò sí oúnjẹ tí ḿmú ara lókun bí èyí tí a jẹ sẹ́nu ẹni lọ.

Kó wó, kó wó, àràbà ò wó; ojú tìrókò.

Kọ̀ǹkọ̀ṣọ̀-ọ́ ní bí a ti ṣe òun tó yìí, òún ṣì ńku èlùbọ́.

Kùtù-kùtù kì í jíni lẹ́ẹ̀mejì; kùtù-kùtù ní ńjẹ́ òwúrọ̀; biri ní ńjẹ́ alẹ́.

Labẹ́-labẹ́ ò bá tìjà wá odò; kanna-kánná ò bá ti ẹ̀kọ wá oko.

Labẹ́-labẹ́ ò bẹ̀rù ìjà.

Lékèélékèé gbàràdá, ó gba tẹlòmíràn mọ.

Lójú-lójú là ńwo ẹni tí a óò kéwì fún.

Máà gbíyè lógún; ti ọwọ́ ẹni ní ńtóni.

“Má kọjá mi Olùgbàlà” kì í ṣe orin à-kúnlẹ̀-kọ.

Màrìwò ò wí fúnra wọn tẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi ńyọ.

Màrìwò ò wojú ẹnìkan, àfi Ọlọ́run.

Mo di arúgbó ọdẹ tí ńtu olú, mo di àgbàlagbà ọdẹ tí ńwa ògòǹgò láàtàn; mo di ògbólógbòó akítì tí ńgba ìbọn lọ́wọ́ ọdẹ.

“Mo kúgbé” lehoro ńdún lóko; “Mo mówó rá” làparò ńdún lábà-a bàbà.

“Mo ṣe é tán” ló níyì; a kì í dúpẹ́ aláṣekù.

Múlele múlèle: ilá tí ò mú lele ò léè so; ikàn tí ò mú lele ò léè wẹ̀wù ẹ̀jẹ̀.

“Ng ó lọ, ng ó lọ!” lobìnrín fi ńdẹ́rù ba ọkùnriń “Bóo lè lọ o lọ” lọkùnrín fi ńdẹ́rù ba obìnrin.

Ní inú ẹ̀gún, ní inú-u gọ̀gọ̀, ọmọ ayò a ṣara bòró.

Ní inú òfíì àti ọ̀láà, ọmọ páńdọ̀rọ̀ ńgbó.

Ní inú òwú la ti ḿbù ṣènì òwú.

Ní ọjọ́ eré nìyà ńdun ọ̀lẹ; kàkà kó wọlé kó jáde a fọwọ́ rọ igi, a pòṣé ṣàrà.

Ní teere, ní tèèrè, Ṣàngó ṣe bẹ́ẹ̀ ó jó wọjà.

.
PreviousContentsNext