Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

I

Ìbẹ̀rù ejò ò jẹ́ ká tẹ ọmọ ejò mọ́lẹ̀.

Ibi gbogbo ní ńrọ àdàbà lọ́rùn.

Ibi gbogbo nilẹ̀ ọ̀wọ̀.

Ibi tí a ní kí gbégbé má gbèé, ibẹ̀ ní ńgbé.

Ibi tí a ní kí tẹ̀tẹ̀ má tẹ̀, ibẹ̀ ní ńtẹ̀.

Ibo ni imú wà sẹnu? Ibo ni Làǹlátẹ̀-ẹ́ wà sí Èrúwà?

Idà kì í lọ kídà má bọ̀.

Ìdẹra ò kan àgbà.

Igi kì í dá lóko kó pa ará ilé.

Igúnnugún pa guuru mádìẹ; kò leè gbe.

Igba eṣinṣin kì í dènà de ọwọ̀.

Igba ẹranko kì í dènà de ẹkùn.

Ìgbà yí làárọ̀? Arúgbó ńkọgba.

Ìgbà yí làárọ̀? Arúgbó ńṣoge.

Ìgbé a gbé ìyàwó kò ṣéé gbé owó.

Igbe kí-ni-ngó-jẹ-sùn ní ḿpọ̀lẹ.

Ìgbín kì í tẹnu mọ́gi kó má gùn ún.

Ìgbín kọ mímì ejò.

Ìjà ò mọ ẹ̀gbọ́n, ó sọ àbúrò dakin.

Ìje òun oore ní ḿmú ọmọ ṣiṣẹ́.

Ìjèṣà ò nídì-i ìṣáná; ilé lọmọ Ọwá ti ńfọnná lọ sóko.

Ìjẹkújẹ kì í pa ahanrandi.

Ikán ò lè rí ṣe lára ìgànná.

Ìkòkò tí yó jẹ ata, ìdí ẹ̀ á gbóná.

Ìkọ́ kì í kọ́ ejò lẹ́sẹ̀.

Ikọ̀ tí ò mọ iṣẹ́-ẹ́ jẹ́ ní ńjẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀mejèe.

Ilá kì í ga ju akórè lọ kó má tẹ̀ ẹ́ ká.

Ilé tí a tóó kun, a kì í bo ìtùfù-u rẹ̀.

Ilé tí a tó lọ sùn lọ́sàn-án, a kì í tó òru lọ sùn ún.

Ìlérí adìẹ, asán ni lójú àwòdì.

Ìlẹ̀kẹ̀-ẹ́ gbé orí àtẹ wu ọ̀lẹ.

Ìlẹ̀kẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́ ò yí olè lójú.

Ìlọrin ò lóòṣà; ẹnu lòòṣà Ìlọrin.

Ìmúmúnàá abìdí sembé-sembé; ìmúmúnàá ò dáná rí, tiná-tiná ní ḿbá kiri.

Iná kì í jó kí ògiri sá.

Iná kì í jó kó wọlé akàn.

Ìpa à ńpoṣè ara ló fi ńsan.

Ìpẹ̀ta lọṣẹ àpọ́n.

Ìpilẹ̀ ọrọ̀-ọ́ lẹ́gbin.

Ìpọ́njú àgbẹ̀ ò ju ọdún kan.

Ìpọ́njú lọmọdé fi ńkọ́Fá, ìgbẹ̀hìn-in rẹ̀ a dẹni.

Ire tí ọwọ́-ọ̀ mi ò tó, ma fi gọ̀ǹgọ̀ fà á.

Ìrèké ti ládùn látọ̀run.

Ìríkúrìí kì í fọ́ ojú.

Irínwó ẹfọ̀n, ẹgbẹ̀rin ìwo, ogún-un Fúlàní, ójì-i bàtà; Ògídíolú ò wẹ̀hìn tó fi lé Adalo lùgbẹ́.

Ìròjú baba ọ̀lẹ.

Ìrókò o-nígun-mẹ́rìn-dín-lógún ò tó erin-ín gbémì, áḿbọ̀ǹtorí ìtóò a-lara-boro-boro.

Ìrònú ìkokò ní yó pa ajá.

Ìrọ́jú ni ohun gbogbo; ojoojúmọ́ ní ńrẹni.

Ìsàlẹ̀ ọrọ̀-ọ́ lẹ́gbin.

Isán ḿbọ́jú, ìtàlá ńwẹsẹ̀.

Iṣẹ́ ajé le, ó tó ọpa.

Ìṣẹ́ kì í ṣe ohun àmúṣeré; ìyà kì í ṣe ohun àmúṣàwàdà.

Iṣẹ́ loògùn ìṣẹ́.

Ìṣẹ́ ńṣẹ́ ọ ò ńrojú; ta ni yó fùn-ún ọ ni oògùn-un rẹ̀?

Ìṣẹ́ ní òun ó kòówó; ìyà-á ní òun ó singbà; réderède-é ní òun ó ṣe onígbọ̀wọ́; ta ní jẹ́ rere nínú-u wọn?

Ìṣẹ́ ò gbẹ́kún, ebí jàre ọ̀lẹ.

Iṣẹ́ ọ̀gẹrọ̀ lọ̀lẹ́ mọ̀-ọ́ ṣe; kò jẹ́ wá iṣẹ́ agbára.

Ìṣẹ́ tó ṣẹ́ ọmọ lógún ọdún, ìyà tó jẹ ọmọ lọ́gbọ̀n oṣù, bí kò pa ọmọ, a sì lẹ́hìn ọmọ.

Iṣẹ́-ajé-ò-gbé-bòji, ọmọ ẹ̀ Òjíkùtù.

Iṣu àtẹnumọ́ kì í jóná; ọ̀kà àtẹnumọ́ kì í mẹrẹ; àwòdì kì í gbé adìẹ à-tẹnu-kunkun-mọ́.

Iṣu ẹni kì í fini pe ọmọdé kó má ta.

Iṣú wà lọ́wọ́ ẹ; ọ̀bẹ́ wà lọ́wọ́ ẹ.

Ìwà ọ̀lẹ ḿba ọ̀lẹ lẹ́rù; ọ̀lẹ́ pàdánù, ó ní aráyé ò fẹ́ràn òun.

Ìwòyí èṣí ewùrà-a baba-à mí ti ta; ìrègún rere ò sí níbẹ̀.

Ìyà tó ńjẹ ọ̀lẹ ò kéré; a-lápá-má-ṣiṣẹ́.

Ìyànjú là ńgbà; bí a ò gbìyànjú bí ọ̀lẹ là ńrí; ojoojúmọ́ ní ńrẹni.

Ìyáwọ́, ìyásẹ̀ lajá fi ńpa ehoro; wàrà-wàrà lẹkùn ńgùn.

.
PreviousContentsNext