Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 4: On perseverance, industry, resilience, self-confidence, self-reliance, resourcefulness, daring, fortitude, and invulnerability

F

Fi gọ̀gọ̀ sílẹ̀ fún ọ̀dáwé; fi ọkọ sílẹ̀ fún onílara.
Leave the hooked stick alone for the leaf plucker; leave the husband alone for the jealous woman.
(If a person will nor share what he or she has, one should simply shun him or her.)

Fífẹ́ la fẹ́ ẹ̀fọ́ tí à ńpè-é ní ọ̀rẹ́ ẹ̀kọ ti ilé oge-é tó oge-é jẹ.
It is only because one loves spinach that one calls it a friend of corn loaf; what the dandy has at home is enough food for him or her.
(That one delights in another person's company is not to say that one cannot do without it.)
Compare Dídùn ló dùn . . .

“Fọ́ ẹ̀kọ ká jọ mu ú,” kò tó ọkọlóbìnrin-ín ṣe ni.
“Prepare the corn pap and let us eat it together” is an indication that the speaker lacks what it takes to be a husband.
(One should not be tentative in exercising one's authority.)
Compare Àgbà tí kò tó ọmọdéé rán níṣẹ́ . . .

.
PreviousContentsNext