Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

W

Wàrà-wàrà là ńyọ oró iná.

Wèrè-é dùn-ún wò, kò ṣé-é bí lọ́mọ.

Wèrè-é yàtọ̀ sí wéré; wéré kì í ṣe wèrè; ìjá yàtọ̀ sí eré.

Wéré-wéré lọmọdé ḿbọ oko èèsì.

Wò mí lójú, wò mí lẹ́ẹ̀kẹ́; ẹni a bá lọ sóde là ńwò lójú.

“Wo ọmọ-ọ̀ mi dè mí”: ó ńlo kíjìpá mẹ́ta gbó; mélòó ni ọlọ́mọ-ọ́ máa lò gbó?

Wolé-wolé kì í wolé agbọ́n láì tẹ́.

Wọ́n ní, “Afọ́jú, o ò tanná alẹ́.” Ó ní àtọ̀sán àtòru, èwo lòún rí níbẹ?

Wọ́n ní, “Afọ́jú, ọmo-ọ̀ ẹ-ẹ́ pẹran.” Ó ní kò dá òun lójú, àfi bí òún bá tọ́ ọ wò.

.
PreviousContents