Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

T

Ta lèèyàn nínú ẹrú Ààrẹ? A ní Ìdaganna la wá wá, ẹ ní Ìdakolo?

Ta ní jẹ́ jẹ ọṣẹ kó fògìrì fọṣọ?

Ta ní mọ̀dí òjò, bí kò ṣe Ṣàngó?

Tábà tí ò dùn, ẹnu ò tà á.

“Tèmi ò ṣòro,” tí kì í jẹ kọ́mọ alágbẹ̀dẹ ní idà.

Tẹni ní ńjọni lójú; eèrà-á bímọ-ọ ẹ̀ ó sọ ọ́ ní òyírìgbí.

Tẹni ntẹni; bí àpọ́n bá sun iṣu a bù fọ́mọ-ọ ẹ̀.

Tẹ̀tẹ́ ní ńṣíwájú eré sísa.

Tìẹ́ sàn, tèmí sàn, lolókùnrùn méjì-í fi ńdìmú.

Tinú ọ̀lẹ lọ̀lẹ ńjẹ; aṣiwèrè èèyàn ni ò mọ èrú tí yó gbà.

.
PreviousContentsNext