Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

I

Ìbéèrè kì í jẹ́ kí ẹni ó ṣìnà; ẹni tí kò lè béèrè ní ńnpọ́n ara ẹ̀ lójú.

Ibi tí a bá ńgbé la ti ńgbàwìn; à-rà-àì-san ni ò sunwọ̀n.

Ibi tí a gbé epo sí a kì í sọ òkò síbẹ̀.

Ibi tí a ti gùn, ibẹ̀ la ti ńrọ̀.

Ibi tí a ti ńjẹun bí ikun bí ikun, a kì í sọ̀rọ̀ bíi kẹ̀lẹ̀bẹ̀ bíi kẹ̀lẹ̀bẹ̀ níbẹ̀.

Ibi tí à ńgbé là ńṣe; bí a bá dé ìlú adẹ́tẹ̀ à di ìkúùkù.

Ibi tí o máa sùn lo tẹ́ ọmọ sí.

Ibi tí òjò-ó ti ńpa igún bọ̀-ọ́ jìnnà; ta ní rán igún níṣẹ́?

Ibi tí òjò-ó bá ọjọ́ ní ńpa á sí.

Ibi tí oníyọ̀nmọ̀ntìí ṣubú sí, ibẹ̀ ló ti tà á tán.

Ibi tí oyín gbé ńhó, tí àdó ńhó, ìfun ò dákẹ́ lásán.

Ìdí òwò ni òwòó gbé tà.

Igún ṣoore ó pá lórí, àkàlà-á ṣoore ó yọ gẹ̀gẹ̀; nítorí ọjọ́ mìíràn kẹni ó má ṣe oore bẹ́ẹ̀ mọ́.

Igúnnugún ò torí abẹ párí.

Ìgbà ara là ḿbúra.

Igbá là ńpa, a kì í pa àwo.

Ìgbà òjò ńlọ, ìgbà ẹ̀rùn ńlọ, a ní ká dí isà eku kó le; ìgbà wo la óò tó wá peku náà?

Ìgbà tí a bá dóko làárọ̀ ẹni.

Ìgbà tí a bá rẹni lòwúrọ̀ ẹni.

Igbá tó gbédè là ḿpè lóṣùwọ̀n.

Ìgbín ìbá má mọ̀-ọ́ jẹ̀ ìbá ti kú síjù.

Ìgbín ìbá má mọ̀-ọ́ jẹ̀ kò tó okòó.

Ìgbín kì í pilẹ̀ aró, àfè ìmòjò kì í pilẹ̀ àràn.

Igbó lẹranko ńgbé.

Ìgbọ̀nwọ́ ti kékeré yọké.

Ìjà ní ńpa onítìjú; ogun ní ḿpa alágbára.

Ijó ní ḿbọ́ṣọ, ìjà ní ḿbọ́ ẹ̀wù.

Ikúdú pa ẹṣin à ńyọ̀; ó ḿbọ̀ wá pa ọmọ èèyàn.

Ilé ajá là ńwá ìwo lọ?

Ilé olóńjẹ là ńdẹ̀bìtì àyà sí.

Ilẹ̀ nìjòkò ńjókòó de ìdí.

Ìlẹ̀kẹ̀ àmúyọ, a kì í sin kádìí tán.

Ìloro là ńwọ̀ ká tó wọlé.

Ìlọ-ọ́ ya, oníbodè Atàdí; wọ́n kó o nílé, wọ́n gbà á lóbìnrin, ọ̀pẹ̀lẹ̀ tó ní òun ó fi wádìí ọ̀ràn, ajá gbé e, ọmọ ẹ̀ tó lé ajá láti gba ọ̀pẹ̀lẹ̀, ó yí sí kàǹga; oníbodè Atàdí wá dáhùn ó ní, “Ìlọ-ọ́ yá.”

Iná èsìsì kì í jóni lẹ́ẹ̀mejì.

Iná kúkú ni yó ba ọbẹ̀ ará oko jẹ́.

Iná tó ńlérí omi á kù sọnù.

Ìpàṣán tí a fi na ìyálé ḿbẹ láàjà fún ìyàwó.

Ìròrẹ́ ò le-è jà ó múlé ti agbọ́n.

Isó inú ẹ̀kú, à-rá-mọ́ra.

Ìṣeǹṣe ewúrẹ́, kágùntàn fiyè síi.

Iṣú ta iṣu ò ta, ọ̀kọ̀ọ̀kan là ńwúṣu lébè.

Ìtórò tó so lóko tí kò fẹ̀hìntì, afẹ́fẹ́ oko ní ńtú u.

Ìwò-o ọlọgbọ́n ò jọ ti aṣiwèrè.

Ìyàwó mi ò sunwọ̀; nítorí ọmọ ni mo ṣe fẹ́ ẹ; ẹni mélòó la ó wìí fún tán?

Ìyàwó sọ ọ̀rọ̀ kan tán: ó ní ìyálé òun a-bẹnu-funfun-bí-ègbodò.

Ìyàwó ṣe ọ̀ràn kan tán; ọkọ ẹ̀-ẹ́ ṣe ọ̀ràn-an nkò-jẹ-mọ́.

.
PreviousContentsNext