Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

Sdot

Ṣàǹgó kì í jà kó mú ilé aró.
Ṣango does not fight and destroy the enclosure for dyeing.
(Some people are beyond the reach of some nemesis.)

Ṣàngó ní òun ní ńkó ọkùnrin suuru bá jà; Èṣù ní bí-i tòun? Ṣàngó ní kí tÈṣù kúrò.
Ṣàngó says he gathers people around him to fight together; Èṣù asks if Ṣàngó includes people like him, and Ṣàngó says Èṣù is the exception.
(No one wants to engage in any venture with an unpredictable trouble maker.)

“Ṣe mí níṣu” ní ńṣíwájú “ẹ kúuṣẹ́” bí?
Does “Give me some yam” go before “Hello there, you working man.”?
(It is bad form to ask people for favors before you say hello to them.)
This is a variant of “Bùn mi níṣu kan” . . .

Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ò ṣéé fọ̀pá na.
The beaded musical gourd is not something to play with a stick.
(Always apply the proper tool to the job.)

Ṣẹ́kẹ́-ṣẹkẹ̀-ẹ́ dára, ṣùgbọ́n alágbẹ̀dẹ ò rọ ọ́ fún ọmọ ẹ̀.
Handcuffs are pretty, but the blacksmith does not fashion them for his own child.
(When trouble is being distributed, one always wishes to exempt one's own people.)

Sútà ò nílé; ìkóríta lÈṣù ńgbé.
Perfidy has no home; the home of Èṣù is the crossroads.
(No one makes room in his or her home for an abomination.)

.
PreviousContentsNext