Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 2: On perspicaciousness (good judgment, perceptiveness), reasonableness, sagacity, savoir-faire, wisdom, and worldly wisdom

K

Kàkà kí ọmọdé pàgbà láyò, àgbà a fi ọgbọ́n àgbà gbé e.
Instead of permitting defeat by a child in a game, an elder should resort to elderly wiles.
(An elder should protect his face and standing by all means available.)

Kì í jẹ́ kí etí ẹni di kì í jẹ kí inú ẹni dùn.
Whatever keeps one from being deaf to certain things keeps one from being happy.
(One should learn to turn a deaf ear to certain things for the sake of one's peace of mind.)

Kì í ṣe gbogbo ẹni tí ńṣe “Ẹni Ọlọ́rún bùn ó bùn mi” là ńfún ní nǹkan.
It is not to every person who says “Whoever has received some bounty from God should give to me” that one gives alms.
(One should be judicious as to those to whom one shows kindness.)

Kí ni à ńwọ̀ nínú-u ṣòkòtò mẹ́ta ọ̀ọ́dúnrún?
What is there to wear in a pair of trousers bought at three for three hundred cowries, or three a penny?
(Much ado about a worthless thing.)

Kí ni fìlà yó ṣe lórí ògógó? Ata ni yó ṣi.
What would a cap be doing atop the ògógó mushroom? Pepper will remove it.
(Superfluous adornments make no sense when one goes to battle or engages in strenuous work.)

Kí ni ìyá aláṣọ ńtà tó yọ ẹgba lọ́wọ́? Ewúrẹ́ ńjẹ wúlìnì?
What is the cloth-selling woman have to sell that she carries a whip in her hand?
Do goats eat woolen fabrics?
(One should not engage in meaningless or unnecessary activities.)

Kékeré egbò ní ngba ewé iyá; àgbà egbò ní ńgba ẹ̀gbẹ̀sì; tilé-wà-tọ̀nà-wá egbò ní ńgba ìgàn aṣọ.
A small sore calls for the balsam tree leaf; a big sore takes an ẹ̀gbẹ̀sì leaf; a huge ulcer calls for a whole bolt of cloth.
(Remedies must fit the complaint.)

Kíkọ́ ni mímọ̀, òwe àjàpá.
Learning is knowing, Àjàpà's proverb.
(To know, one must learn.) [79]

Kéré-kéré leku ńjawọ; díẹ̀-díẹ̀ leèrà ḿbọ́ ìyẹ́.
Bit by bit the rat consumes the leather; gently gently the ant sloughs its skin.
(One should use caution in all one's enterprises.)

Kò sí alámàlà tí ńsọ pé tòun ò yi; aládàlú nìkan ló sòótọ́.
There is no yam-flower meal seller who will advertise her ware as fluffy; the àdàlú seller alone speaks the truth.
(One puts the best face on one's own affairs.)
Compare Kò sí aláásáà . . . [80]

Kò sí aláásáà tí ńta ìgbokú; gbogbo wọn ní ńta oyin.
There is no snuff seller who will advertise her ware as awful; they all say they are selling honey.
(Everybody presents himself/herself in the best light.)
Compare Kò sí alámàlà . . .

Kò sí ẹni tí kò mọ ọgbọ́n-ọn ká fẹran sẹ́nu ká wá a tì.
There is nobody who does not know the trick of putting meat in the mouth and making it disappear.
(Nobody is a complete fool.)

Kókó ló kọ́kọ́ dé orí, tàbí orí ló kọ́kọ́ dé kókó?
Was it the lump that first got to the head, or the head that first got to the lump?
(A chastisement for someone attempting to reverse the order of precedence.)

Kóǹkólóyo: èyí tó ní tèmi.
A rather small thing: this is enough for me.
(However small it is “usually a child”, one is glad to have it.)

Kóró-kóró là ńdá Ifá adití.
Very loud is the way one consults Ifá for a deaf person.
(One should match one's actions to the circumstances; or one should err on the side of repetitiousness when one cautions an obstinate person.)

Kùbẹ̀rẹ̀, ká roko ìpére. Ó ní èyí tí òún lọ òun òì bọ̀.
“Kubẹrẹ, let us go to the bush where small snails are picked.” He said the last such trip he went on, he has not returned from it.
(When one has not recovered from the consequences of a venture, one is not ready to embark on another one.)

 

79. The anecdote connected with the proverb states that once Àjàpá (Tortoise and trickster) made a basket so speedily that people asked in astonishment how it did it, and it responded with the proverb.  [Back to text]

.
PreviousContentsNext