Contents | Display Settings | Font Settings | About

Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraint

Gb

“Gbà jẹ” ò yẹ àgbà.

“Gbà mí, gbà mí!” ò yẹ àgbà; àgbà kì í ṣe ohun àlémú.

“Gbà mí, gbà mí!” ò yẹ eégún; “ẹran ńlémi bọ̀” ò yẹ ọdẹ.

“Gba wèrè,” “Ng ò gba wèrè” lọjà-á fi ńhó.

Gbogbo èèyàn ní ńsunkún-un Bánjọ; ṣùgbọ́n Bánjọ ò sunkún ara ẹ̀.

Gbogbo ẹgbẹ́ ńjẹ Má-yẹ̀-lóyè, ò ńjẹ Sáré-pẹgbẹ́.

Gbogbo ọ̀rọ̀ ní ńṣojú èké.

Gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n kan ò sí, àfi ẹni tó bá ńti ara ẹ̀.

.
PreviousContentsNext