Contents | Display Settings | Font Settings | About | |||||||
Part 1: On humility, self-control, self-knowledge, self-respect, and self-restraintI
Ìbàjẹ́ ọjọ́ kan ò tán bọ̀rọ̀.
Ibi tí a bá pè lórí, a kì í fi tẹlẹ̀.
Ibi tí a fi ara sí lara ńgbé.
Ibi tí a fi iyọ̀ sí ló ńṣomi sí.
Ibi tí a pè lórí ní ńhurun.
Ibi tí a ti mú ọ̀lẹ ò kúnná; ibi tí a ti mú alágbáraá tó oko-ó ro.
Ibi tí a ti ńpìtàn ká tó jogún, ká mọ̀ pé ogún ibẹ̀ ò kanni.
Ibi tí ayé bá ẹni ni a ti ńjẹ ẹ̀.
Ìbọ́n dídá olówó ló ní kíwọ̀fà rín rín rín kó sọ àdá nù.
Idà ahun la fi ńpa ahun.
Idà ńwó ilé ara ẹ̀ ó ní òún ḿba àkọ̀ jẹ́.
Ìdí méjèèjìí tó olúwa rẹ̀-ẹ́ jókòó.
Igúnnugún bà lé òrùlé; ojú tó ilé ó tó oko.
Ìgbà tí ṣìgìdìí bá fẹ́ ṣe eré ẹ̀tẹ́ a ní kí wọ́n gbé òun sójò.
Ìgbà wo ni Mákùú ò níí kú? Mákùú ò mọ awo ó ḿbú ọpa; Mákùú ò mọ ìwẹ̀ ó ḿbọ́ sódò.
Ihò wo lèkúté ńgbé tó ní iṣẹ́ ilé ńdíwọ́?
Ìjàkùmọ̀ kì í rin ọ̀sán, ẹni a bí ire kì í rin òru.
Ìjàlọ ò lè gbé òkúta.
Ìjokòó ẹni ní ḿmúni da ewé ẹ̀kọ nù.
Ìjọba ńpè ọ́ o ní ò ḿmu gààrí lọ́wọ́; ta ní ni ọ́, ta ní ni omi tí o fi ḿmu gààrí?
Ilè-ni-mo-wà kì í jẹ̀bi ẹjọ́.
Ilé kì í jó kí baálé ilé tàkakà.
Ilé kì í jó kí oorun kun ojú.
Ìlù kan ò tó Ègùn jó; bí a bá lù fún un a máa lu àyà.
Iná ńjó ògiri ò sá, ó wá ńgbá gẹẹrẹ gẹẹrẹ sómi.
Inú burúkú làgbà ńní, àgbà kì í ní ojú burúkú.
Ipa ọgbẹ́ ní ńsàn; ipa ohùn kì í sàn.
Ìpàkọ́ onípàkọ́ là ńrí; eniẹlẹ́ni ní ńrí tẹni.
Ìpéǹpéjú ò ní enini; àgbàlagbà irùngbọ̀n ò ṣe òlòó.
Ìrẹ́jẹ ò sí nínúu fọ́tò; bí o bá ṣe jókòó ni o ó bàá ara-à rẹ.
Irú aṣọ ò tán nínu àṣà.
Irú erin ò tán ní Àlọ́.
Ìrùkẹ̀rẹ̀ kì í yan Ifá lódì; oge, dúró o kí mi.
Ìsáǹsá ò yọ ẹ̀gún; ìsáǹsá kì í káwo ọbẹ̀.
Ìṣẹ̀ ò ti ibìkan mú ẹni; ìyà ò tibìkan jẹ èèyàn; bí o bá rìnrìn òṣì, bí o bá ojú ìṣẹ́ wọ̀lú, igbá-kúgbá ni wọn ó fi bu omi fún ẹ mu.
Ìtàkùn tó tó ọ̀pẹ kò tó pé kérin má lọ; ìtàkùn tó pé kérin má lọ Àlọ́, tòun terin ní ńlọ.
Ìwà ní ńjọ oníwà lójú.
Ìwọ̀fà ní ḿmú ìwọ̀fà jó.
Ìwọ̀n eku nìwọ̀n ìtẹ́; olongo kì í gbé tìmùtìmù.
Ìwọ̀sí ní Xba ilé àgbà jẹ́.
Ìyàwó tó na ọmọ ọbàkan, ọ̀rọ̀ ló fẹ́ gbọ́.
|
|||||||